Native Bible

Deuteronomy 28:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò.

Deuteronomy 28:26 in English

Deuteronomy 28:26 · Berean Standard Bible

Your corpses will be food for all the birds of the air and beasts of the earth, with no one to scare them away.

Context

24Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run. 25Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé. 26Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò. 27Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra. 28Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.