Deuteronomi 28:28
Deuteronomy 28:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.
Deuteronomy 28:28 in English
Deuteronomy 28:28 · Berean Standard Bible
The LORD will afflict you with madness, blindness, and confusion of mind,
Context
26Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò. 27Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra. 28Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà. 29Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ tálẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́. 30Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ́ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èso rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.