Deuteronomi 22:5
Deuteronomy 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.
Deuteronomy 22:5 in English
Deuteronomy 22:5 · Berean Standard Bible
A woman must not wear men’s clothing, and a man must not wear women’s clothing, for whoever does these things is detestable to the LORD your God.
Context
3Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀. 4Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. 5Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí. 6Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ. 7Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.