Deuteronomi 22:7
Deuteronomy 22:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.
Deuteronomy 22:7 in English
Deuteronomy 22:7 · Berean Standard Bible
You may take the young, but be sure to let the mother go, so that it may be well with you and that you may prolong your days.
Context
5Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí. 6Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ. 7Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn. 8Nígbà tí o bá kọ́ ilé tuntun, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má ba à mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé. 9Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èso oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èso ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.