Native Bible

Deuteronomy 22:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.

Deuteronomy 22:4 in English

Deuteronomy 22:4 · Berean Standard Bible

If you see your brother’s donkey or ox fallen on the road, you must not ignore it; you must help him lift it up.

Context

2Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá. Nígbà náà ni kí o fi fún un. 3Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀. 4Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. 5Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí. 6Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.