Deuteronomi 20:10
Deuteronomy 20:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó bá súnmọ́ iwájú láti dojúkọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́.
Deuteronomy 20:10 in English
Deuteronomy 20:10 · Berean Standard Bible
When you approach a city to fight against it, you are to make an offer of peace.
Context
8Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé, “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.” 9Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀. 10Nígbà tí ó bá súnmọ́ iwájú láti dojúkọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́. 11Tí wọ́n bá dá ọ lóhùn àlàáfíà, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́. 12Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbóguntì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.