Native Bible

Deuteronomy 2:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé,

Deuteronomy 2:26 in English

Deuteronomy 2:26 · Berean Standard Bible

So from the Wilderness of Kedemoth I sent messengers with an offer of peace to Sihon king of Heshbon, saying,

Context

24“Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á. 25Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.” 26Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé, 27“Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì. 28Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sá à jẹ́ kí a rìn kọjá:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.