Deuteronomi 2:24
Deuteronomy 2:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á.
Deuteronomy 2:24 in English
Deuteronomy 2:24 · Berean Standard Bible
“Arise, set out, and cross the Arnon Valley. See, I have delivered into your hand Sihon the Amorite, king of Heshbon, and his land. Begin to take possession of it and engage him in battle.
Context
22Bákan náà ni Olúwa ṣe fún àwọn ọmọ Esau, tí wọ́n ń gbé ní Seiri, nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní. 23Nípa ti àwọn ará Affimu, tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèké dé Gasa, àwọn ará Kaftorimu, tí wọ́n jáde láti Krete wá ni ó pa wọ́n run, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.) 24“Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á. 25Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.” 26Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.