Deuteronomi 17:13
Deuteronomy 17:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́.
Deuteronomy 17:13 in English
Deuteronomy 17:13 · Berean Standard Bible
Then all the people will hear and be afraid, and will no longer behave arrogantly.
Context
11Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín. 12Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní Israẹli. 13Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́. 14Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.” 15Ẹ rí i dájú pé ọba tí Olúwa Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn. Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrín àwọn arákùnrin yín. Ẹ má ṣe fi àjèjì jẹ ọba lórí i yín: àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.