Deuteronomi 17:12
Deuteronomy 17:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní Israẹli.
Deuteronomy 17:12 in English
Deuteronomy 17:12 · Berean Standard Bible
But the man who acts presumptuously, refusing to listen either to the priest who stands there to serve the LORD your God, or to the judge, must be put to death. You must purge the evil from Israel.
Context
10Kí ìwọ kí ó sì ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ti àwọn ará ibi tí Olúwa yóò yàn náà yóò fihàn ọ, kí ìwọ kí ó sì máa kíyèsí àti máa ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí wọn kọ́ ọ. 11Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín. 12Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní Israẹli. 13Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́. 14Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.