Native Bible

Daniel 8:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.

Daniel 8:18 in English

Daniel 8:18 · Berean Standard Bible

While he was speaking with me, I fell into a deep sleep, with my face to the ground. Then he touched me, helped me to my feet,

Context

16Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gabrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.” 17Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bà mí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.” 18Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi. 19Ó sọ wí pé, “Èmi yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn. 20Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Media àti Persia.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.