Native Bible

Daniel 8:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Media àti Persia.

Daniel 8:20 in English

Daniel 8:20 · Berean Standard Bible

The two-horned ram that you saw represents the kings of Media and Persia.

Context

18Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi. 19Ó sọ wí pé, “Èmi yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn. 20Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Media àti Persia. 21Òbúkọ onírun náà ni ọba Giriki, ìwo ńlá ti ó wà láàrín ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́. 22Ìwo mẹ́rin mìíràn sì dìde dúró dípò ọ̀kan tí ó ṣẹ́, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde nínú orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò ní ní irú agbára kan náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.