Native Bible

Daniel 8:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bà mí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”

Daniel 8:17 in English

Daniel 8:17 · Berean Standard Bible

As he came near to where I stood, I was terrified and fell facedown. “Son of man,” he said to me, “understand that the vision concerns the time of the end.”

Context

15Nígbà tí èmi Daniẹli, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú mi. 16Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gabrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.” 17Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bà mí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.” 18Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi. 19Ó sọ wí pé, “Èmi yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.