Daniẹli 8:15
Daniel 8:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí èmi Daniẹli, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú mi.
Daniel 8:15 in English
Daniel 8:15 · Berean Standard Bible
While I, Daniel, was watching the vision and trying to understand it, there stood before me one having the appearance of a man.
Context
13Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúṣẹ—ìran nípa ẹbọ ojoojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó mú ìsọdahoro wa, àní láti fi ibi mímọ́ àti ogun ọ̀run fún ni ní ìtẹ̀mọ́lẹ̀?” 14Ó sọ fún mi pé, “Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún (2,300) alẹ́ àti òwúrọ̀; lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́.” 15Nígbà tí èmi Daniẹli, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú mi. 16Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gabrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.” 17Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bà mí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.