Daniẹli 5:10
Daniel 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro.
Daniel 5:10 in English
Daniel 5:10 · Berean Standard Bible
Hearing the outcry of the king and his nobles, the queen * entered the banquet hall. “O king, may you live forever!” she said. “Do not let your thoughts terrify you, or your face grow pale.
Context
8Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le è ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 9Nígbà náà ni Belṣassari ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú sí i. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè Belṣassari. 10Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro. 11Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ ń gbé inú rẹ̀. Ní ìgbà ayé e baba à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti ọlọ́run òun ni ọba Nebukadnessari, baba rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn apidán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ. 12Ọkùnrin náà ni Daniẹli ẹni tí ọba ń pè ní Belṣassari, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá da ojú rú, ránṣẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.