Native Bible

Daniel 5:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ ń gbé inú rẹ̀. Ní ìgbà ayé e baba à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti ọlọ́run òun ni ọba Nebukadnessari, baba rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn apidán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ.

Daniel 5:11 in English

Daniel 5:11 · Berean Standard Bible

There is a man in your kingdom who has the spirit of the holy gods in him. In the days of your father he was found to have insight, intelligence, and wisdom like that of the gods. Your father, King Nebuchadnezzar, appointed him chief of the magicians, enchanters, astrologers, and diviners. Your own father, the king,

Context

9Nígbà náà ni Belṣassari ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú sí i. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè Belṣassari. 10Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro. 11Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ ń gbé inú rẹ̀. Ní ìgbà ayé e baba à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti ọlọ́run òun ni ọba Nebukadnessari, baba rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn apidán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ. 12Ọkùnrin náà ni Daniẹli ẹni tí ọba ń pè ní Belṣassari, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá da ojú rú, ránṣẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.” 13Nígbà náà ni a mú Daniẹli wá síwájú ọba, ọba sì sọ fún un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan lára àwọn tí baba mi mú ní ìgbèkùn láti Juda!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.