Native Bible

Daniel 3:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.

Daniel 3:27 in English

Daniel 3:27 · Berean Standard Bible

and when the satraps, prefects, governors, and royal advisers had gathered around, they saw that the fire had no effect on the bodies of these men. Not a hair of their heads was singed, their robes were unaffected, and there was no smell of fire on them.

Context

25Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ ọlọ́run.” 26Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!” Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná. 27Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá. 28Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn. 29Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀-èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.