Native Bible

Daniel 3:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.

Daniel 3:28 in English

Daniel 3:28 · Berean Standard Bible

Nebuchadnezzar declared, “Blessed be the God of Shadrach, Meshach, and Abednego, who has sent His angel * and delivered His servants who trusted in Him. They violated the king’s command and risked their lives rather than serve or worship any god except their own God.

Context

26Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!” Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná. 27Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá. 28Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn. 29Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀-èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.” 30Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.