Native Bible

Daniel 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi.

Daniel 2:8 in English

Daniel 2:8 · Berean Standard Bible

The king replied, “I know for sure that you are stalling for time, because you see that my word is final.

Context

6Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀. Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” 7Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀.” 8Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi. 9Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” 10Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.