Native Bible

Daniel 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

Daniel 2:9 in English

Daniel 2:9 · Berean Standard Bible

If you do not tell me the dream, there is only one decree for you. You have conspired to speak before me false and fraudulent words, hoping the situation will change. Therefore tell me the dream, and I will know that you can give me its interpretation.”

Context

7Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀.” 8Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi. 9Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” 10Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀. 11Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fihan ọba àfi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrín ènìyàn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.