Daniẹli 2:6
Daniel 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀. Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”
Daniel 2:6 in English
Daniel 2:6 · Berean Standard Bible
But if you tell me the dream and its interpretation, you will receive from me gifts and rewards and great honor. So tell me the dream and its interpretation.”
Context
4Nígbà náà ni àwọn awòràwọ̀ dá ọba lóhùn ní èdè Aramaiki pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Sọ àlá yìí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àwa yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.” 5Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, “Ohun náà ti kúrò lórí mi, tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn. 6Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀. Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” 7Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀.” 8Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.