Daniẹli 2:42
Daniel 2:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan.
Daniel 2:42 in English
Daniel 2:42 · Berean Standard Bible
And as the toes of the feet were partly iron and partly clay, so this kingdom will be partly strong and partly brittle.
Context
40Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tókù. 41Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. 42Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan. 43Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀. 44“Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.