Daniẹli 2:43
Daniel 2:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀.
Daniel 2:43 in English
Daniel 2:43 · Berean Standard Bible
As you saw the iron mixed with clay, so the peoples * will mix with one another, but will not hold together any more than iron mixes with clay.
Context
41Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. 42Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan. 43Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀. 44“Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.” 45Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́.
“Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.