Native Bible

Daniel 2:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

Daniel 2:23 in English

Daniel 2:23 · Berean Standard Bible

To You, O God of my fathers, I give thanks and praise, because You have given me wisdom and power. And now You have made known to me what we have requested, for You have made known to us the dream of the king.”

Context

21Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye. 22Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà. 23Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.” 24Nígbà náà ni Daniẹli tọ́ Arioku lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Babeli run, Daniẹli wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Babeli run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sísọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.” 25Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.