Daniẹli 11:22
Daniel 11:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ-aládé ti májẹ̀mú náà ni a ó parun.
Daniel 11:22 in English
Daniel 11:22 · Berean Standard Bible
Then a flood of forces will be swept away before him and destroyed, along with a prince of the covenant.
Context
20“Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun. 21“Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè. 22Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ-aládé ti májẹ̀mú náà ni a ó parun. 23Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba. 24Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbóguntì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógun ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.