Native Bible

Daniel 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbóguntì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógun ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.

Daniel 11:24 in English

Daniel 11:24 · Berean Standard Bible

In a time of peace, he will invade the richest provinces and do what his fathers and forefathers never did. He will lavish plunder, loot, and wealth on his followers, and he will plot against the strongholds—but only for a time.

Context

22Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ-aládé ti májẹ̀mú náà ni a ó parun. 23Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba. 24Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbóguntì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógun ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni. 25“Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ sókè sí ọba gúúsù. Ọba gúúsù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní le è dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbèrò sí i. 26Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun, a ó gbá ogun rẹ̀ dànù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.