Amosi 6:3
Amos 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí.
Amos 6:3 in English
Amos 6:3 · Berean Standard Bible
You dismiss the day of calamity and bring near a reign of violence.
Context
1Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria
àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè
tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá. 2Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.
Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini.
Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?
Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí? 3Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí. 4Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn
ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ
ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ. 5Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.