Native Bible

Amos 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.

Amos 6:4 in English

Amos 6:4 · Berean Standard Bible

You lie on beds inlaid with ivory, and lounge upon your couches. You dine on lambs from the flock and calves from the stall.

Context

2Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini. Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí? 3Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí. 4Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ. 5Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin. 6Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.