Amosi 6:11
Amos 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà, Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú, àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́.
Amos 6:11 in English
Amos 6:11 · Berean Standard Bible
For the LORD gives a command: “The great house will be smashed to pieces, and the small house to rubble.”
Context
9Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú. 10Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.” 11Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú,
àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́. 12Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò. 13Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari,
ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.