Amosi 6:12
Amos 6:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
Amos 6:12 in English
Amos 6:12 · Berean Standard Bible
“Do horses gallop on the cliffs? Does one plow the sea * with oxen? But you have turned justice into poison and the fruit of righteousness into wormwood—
Context
10Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.” 11Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú,
àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́. 12Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò. 13Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari,
ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?” 14Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,
wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,
láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.