Amosi 5:20
Amos 5:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀? Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
Amos 5:20 in English
Amos 5:20 · Berean Standard Bible
Will not the Day of the LORD be darkness and not light, even gloom with no brightness in it?
Context
18Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́
nítorí ọjọ́ Olúwa
kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?
Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́. 19Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún,
tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.
Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ
tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀
tí ejò sì bù ú ṣán. 20Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?
Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀. 21“Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín,
Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín. 22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá.
Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.
Èmi kò ní náání wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.