Amosi 1:12
Amos 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò rán iná sí orí Temani, tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”
Amos 1:12 in English
Amos 1:12 · Berean Standard Bible
So I will send fire upon Teman to consume the citadels of Bozrah.”
Context
10Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire,
tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.” 11Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu,
àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,
Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù,
ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí,
ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́, 12Èmi yóò rán iná sí orí Temani,
tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.” 13Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni,
àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi
kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn. 14Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba
èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run
pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun,
pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.