Native Bible

Acts 9:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè.

Acts 9:41 in English

Acts 9:41 · Berean Standard Bible

Peter took her by the hand and helped her up. Then he called the saints and widows and presented her to them alive.

Context

39Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà, gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn. 40Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. 41Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè. 42Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́. 43Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.