Native Bible

Acts 9:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó.

Acts 9:40 in English

Acts 9:40 · Berean Standard Bible

Then Peter sent them all out of the room. He knelt down and prayed, and turning toward her body, he said, “Tabitha, get up!” She opened her eyes, and seeing Peter, she sat up.

Context

38Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.” 39Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà, gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn. 40Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. 41Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè. 42Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.