Native Bible

Acts 8:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti se ìrìbọmi?”*

Acts 8:36 in English

Acts 8:36 · Berean Standard Bible

As they traveled along the road and came to some water, the eunuch said, “Look, here is water! What is there to prevent me from being baptized?”*

Context

34Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” 35Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìnrere ti Jesu fún un. 36Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti se ìrìbọmi?”* 38Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀. 39Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú, omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.