Ìṣe àwọn Aposteli 8:39
Acts 8:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú, omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.
Acts 8:39 in English
Acts 8:39 · Berean Standard Bible
When they came up out of the water, the Spirit of the Lord carried Philip away, and the eunuch saw him no more, but went on his way rejoicing.
Context
36Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti se ìrìbọmi?”* 38Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀. 39Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú, omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀. 40Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìyìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.
8.36 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ìrìbọmi? 37 Filipi sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitiisi rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jesu Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.