Ìṣe àwọn Aposteli 8:34
Acts 8:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?”
Acts 8:34 in English
Acts 8:34 · Berean Standard Bible
“Tell me,” said the eunuch, “who is the prophet talking about, himself or someone else?”
Context
32Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:
“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;
àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan. 33Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún.
Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?
Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.” 34Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” 35Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìnrere ti Jesu fún un. 36Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti se ìrìbọmi?”*
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.