Native Bible

Acts 4:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

Acts 4:24 in English

Acts 4:24 · Berean Standard Bible

When the believers heard this, they lifted up their voices to God with one accord. “Sovereign Lord,” they said, “You made the heaven and the earth and the sea and everything in them.

Context

22Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ àmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ. 23Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. 24Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 25Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé: “ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú, àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán? 26Àwọn ọba ayé dìde, àti àwọn ìjòyè kó ara wọn jọ sí Olúwa, àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.