Ìṣe àwọn Aposteli 4:22
Acts 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ àmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ.
Acts 4:22 in English
Acts 4:22 · Berean Standard Bible
For the man who was miraculously healed was over forty years old.
Context
20Àwa kò lè ṣàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.” 21Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe. 22Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ àmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ. 23Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. 24Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.