Ìṣe àwọn Aposteli 4:11
Acts 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni “ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’
Acts 4:11 in English
Acts 4:11 · Berean Standard Bible
This Jesus is ‘the stone you builders rejected, which has become the cornerstone.’*
Context
9Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá, 10kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá. 11Èyí ni
“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’ 12Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.” 13Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.