Ìṣe àwọn Aposteli 4:13
Acts 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé.
Acts 4:13 in English
Acts 4:13 · Berean Standard Bible
When they saw the boldness of Peter and John and realized that they were unschooled, ordinary men, they marveled and took note that these men had been with Jesus.
Context
11Èyí ni
“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’ 12Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.” 13Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé. 14Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbèrò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.