Native Bible

Acts 25:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú.

Acts 25:15 in English

Acts 25:15 · Berean Standard Bible

While I was in Jerusalem, the chief priests and elders of the Jews presented their case and requested a judgment against him.

Context

13Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu. 14Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú. 15Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú. 16“Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn. 17Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.