Ìṣe àwọn Aposteli 25:14
Acts 25:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú.
Acts 25:14 in English
Acts 25:14 · Berean Standard Bible
Since they were staying several days, Festus laid out Paul’s case before the king: “There is a certain man whom Felix left in prison.
Context
12Lẹ́yìn tí Festu ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pe, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Kesari. Ní ọ̀dọ̀ Kesari ni ìwọ ó lọ!” 13Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu. 14Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú. 15Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú. 16“Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.