Ìṣe àwọn Aposteli 25:17
Acts 25:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá.
Acts 25:17 in English
Acts 25:17 · Berean Standard Bible
So when they came here with me, I did not delay. The next day I sat on the judgment seat and ordered that the man be brought in.
Context
15Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú. 16“Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn. 17Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá. 18Nígbà tí àwọn olùfisùn náà dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn. 19Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.