Ìṣe àwọn Aposteli 24:8
Acts 24:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ìwọ fúnra rẹ̀ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínní lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀sùn rẹ̀ kàn án.”
Acts 24:8 in English
Acts 24:8 · Berean Standard Bible
By examining him yourself, you will be able to learn the truth about all our charges against him.”
Context
5“Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrín gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Nasarene, 6ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹmpili jẹ́.* 8Nígbà tí ìwọ fúnra rẹ̀ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínní lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀sùn rẹ̀ kàn án.” 9Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí. 10Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Paulu sì dáhùn wí pe, “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀tayọ̀ wí tí ẹnu mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.