Ìṣe àwọn Aposteli 24:5
Acts 24:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrín gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Nasarene,
Acts 24:5 in English
Acts 24:5 · Berean Standard Bible
We have found this man to be a pestilence, stirring up dissension among the Jews all over the world. He is a ringleader of the sect of the Nazarenes,
Context
3Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Feliksi ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo. 4Ṣùgbọ́n kí èmi má ba á dá ọ dúró pẹ́ títí, mo bẹ̀ ọ́ kí o fi ìyọ́nú rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu wa. 5“Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrín gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Nasarene, 6ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹmpili jẹ́.* 8Nígbà tí ìwọ fúnra rẹ̀ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínní lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀sùn rẹ̀ kàn án.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.