Native Bible

Acts 24:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Feliksi ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo.

Acts 24:3 in English

Acts 24:3 · Berean Standard Bible

In every way and everywhere, most excellent Felix, we acknowledge this with all gratitude.

Context

1Lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún Anania olórí àlùfáà náà sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn alàgbà àti ẹnìkan, Tertulu agbẹjọ́rò, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ẹjọ́ Paulu fún baálẹ̀. 2Nígbà tí a sí tí pè Paulu jáde, Tertulu gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Feliksi ó wí pé, “Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ láti ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsùn rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí. 3Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Feliksi ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo. 4Ṣùgbọ́n kí èmi má ba á dá ọ dúró pẹ́ títí, mo bẹ̀ ọ́ kí o fi ìyọ́nú rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu wa. 5“Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrín gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Nasarene,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.