Ìṣe àwọn Aposteli 23:18
Acts 23:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”
Acts 23:18 in English
Acts 23:18 · Berean Standard Bible
So the centurion took him to the commander and said, “Paul the prisoner sent and asked me to bring this young man to you. He has something to tell you.”
Context
16Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu. 17Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.” 18Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun.
Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.” 19Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?” 20Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.