Native Bible

Acts 23:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.

Acts 23:20 in English

Acts 23:20 · Berean Standard Bible

He answered, “The Jews have agreed to ask you to bring Paul to the Sanhedrin tomorrow on the pretext of acquiring more information about him.

Context

18Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.” 19Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?” 20Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀. 21Nítorí náà má ṣe gbọ́ tiwọn, nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsin yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.” 22Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.