Ìṣe àwọn Aposteli 23:16
Acts 23:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.
Acts 23:16 in English
Acts 23:16 · Berean Standard Bible
But when the son of Paul’s sister heard about the plot,* he went into the barracks and told Paul.
Context
14Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu. 15Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.” 16Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu. 17Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.” 18Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun.
Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.